Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?Àpẹrẹ
Ní Ìparí
Tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò gbogbo ohun tí a ti kọ́ tí a sì ti jíròrò lé láti bí ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, njẹ́ ọkàn rẹ wa ń pòngbẹ láti mọ ìfẹ́ tòótọ́ ati láti fẹ́ràn Olúwa nítòótọ́? A nílò Olúwa. Òun nìkan ló lè fi ohun tó jẹ́ ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn hàn wá, yóò sì tún kọ́ wa ní ọ̀nà tí a ó fi já ẹ̀ṣẹ̀ tó so mọ́ wa típẹ́típẹ́ sọnú. Pípa ara ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ohun tí a níláti máa ṣe títí ayé. Ó túmọ̀ sí pé á nílátí máa gbé ìfẹ́ ti ara tì LÓJOOJÚMỌ́, kí á sì máa "rìn pẹ̀lú ìgbàgbọ́". A ní láti máa Pa Òtítọ́ Mọ́ Lọ́kàn Wa, kí òtítọ́ sì jẹ́ ìhùwàsí wa lójoojúmọ́. A gbọ́dọ̀ bọ́ agbádá irọ́, ẹran ara, èṣù àti ayé sọnù, kí á gbé agbádá òtítọ́ tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ nípa ìrànlọ́wọ́ ti È̩mí Mímọ́. Bí a bá ṣe lè gbé gbogbo ìfẹ́kúfẹ̀ àti ìrọ̀rùn ẹ̀ṣẹ̀ jù sẹ́gbẹ̀ kan tó ni a ó ṣe lè gbádùn ìwàláàyè àti ayọ̀ Krístì tó, bẹ́ẹ̀ náá ni àfẹ́rí wa fún Un yó máa gbòòrò si. Ayé wa yóò yí padà bí a ti ń tún ọkàn àti ẹ̀mí wa ṣe. A ó ní ìfẹ́ láti gbé ayé ẹ̀ṣẹ̀ tì, a ó sì dìrọ̀ mọ́ ìtùnú àti ọ̀nà Krístì tí yó mú wa mọ ayọ̀ atì ìgbádùn tó wà nínú ìfẹ́ òtítọ́. A ó ní ìrírí ìfẹ Rẹ̀ nínú wa, àti nípasẹ̀ ìrírí yìí, ète Ọlọ́run fún wa yóò wá sí ìmúṣẹ bí a ṣe kọ ọ́ nínú Katikísímù ti Westminster pé: Kínni kókó òpín ènìyàn? Kókó òpin ẹ̀dá ènìyàn ni láti f'ògo fún Ọlọ́run kí á sì gbádùn Rẹ̀ títí ayé!
Ẹ jẹ́ k'á gbàdúrà, "Mo nífẹ̀ Rẹ Olúwa, nítorí pé ò ń gbọ́ ohùn mi àti ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú. A ti tú ìfẹ́ Rẹ sínú ọkàn mi nípasẹ̀ È̩mí Mímọ́ tí a ti fi fún mi. O ṣeun o, Olúwa!"
Pípa Ọ̀rọ̀ Òtítọ́ Mọ́ Sínú Ọkàn:
Láti òní lọ, máa yan àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí oó máa fi sọ́kàn.
Pípa ẸRAN ARA:
È̩ṣẹ̀ wo ni ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí o kọ sílẹ̀ ń báá wí nínú ayé rẹ?
Mímú Òtítọ́ Wá Sí Gbangba:
Àwọ́n nnkan wo ní pàtó lo nílò láti jọ̀wọ́ nínú èrò rẹ, ìṣesí rẹ àti ìhùwàsí rẹ kí ayé rẹ k'ó lè bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run?

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ yìí làti Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend ṣe àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ìfẹ́ ní ìlànà Bíbélì àti bí a ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.thistlebendministries.org