Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?Àpẹrẹ
A Yí Ìfẹ́ Po
Gẹ́gẹ́ bíi St. Augustine a lè sọ pé ìfẹ́ ni olúborí. Ṣùgbọ́n a tún lè sọ bíi ti Augustine pé a lè ba ohun rere tí Ọlọ́run bá fúnni jẹ́; èyí gan an ni ìtumọ̀ ibi. Nítorí nàà a máa ńyí ìfẹ́ po tí yíó sì máa wá ohun ti ara rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀ alánìkànjọpọ́n ni wá, a sì ń gbé nínú ayé tí ó jẹ́ ti ànìkànjọpọ́n. Bí a bá ń ro ti ara wa nìkan, à ńpàdánù ìfẹ́ Rẹ̀.
A kò ní fẹ́ pàdánù ohun tí ó wà níwájú wa nítorí ẹ̀rù tàbí ìgbéraga tàbí àìgbàgbọ́. A kò ní fẹ́ kọjá lọ nínú ayé pẹlú gbogbo ìgbòkègbodò rẹ̀ kí a wá dé òpin kí a tóó mọ̀ pé a ṣìnà.
Òwe kan tí ó ní oríṣiríṣi ẹ̀dà káàkiri bí ọdún ṣe ńyí lu'ra, kìlọ̀ fún wa jẹ́jẹ́ pé odò tí a bá f'ohú r'énà a máa gbé ní lọ.
Láìsí ìṣò, kò sí bàtà,
Láìsí bàtà, kò sí ẹṣin,
Láìsí ẹṣin, kò sí ẹlẹsin,
Láìsí ẹlẹṣin, kò sí ìfọ̀rọ̀ránṣẹ́,
Láìsí ìfọ̀rọ̀ránṣẹ́, kò sí ogun,
Láìsí ogun, kò sí ìjà,
Láìsí ìjà, kò sí ìjọba,
Látàrí àìsí ìṣó, a pàdánù ayé.
A lè gbà wá là kí a sì rí ọ̀run wọ̀ kí a tóó mọ̀ pé a kò j'aládùn ìfẹ́ Rẹ̀ ní kíkún gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ṣètò rẹ̀ nínú ayé yìí. Amy Carmichael so pé: "Julian ti Norwich [ní ọdún 1300’s] kọ̀wé pé: 'Ìfẹ́ Ọlọ́run ní pé kí a gba ìtùnú Rẹ̀ bí a bá ṣe lè gbà á tó, Ó tún fẹ́ kí a gbé gbogbo ìṣòro wa fúyé, kí a má sì kó wọn lé'yà. Bẹ́ẹ̀ni, nítorí "ayọ̀ ńbọ̀ l'òwúrọ̀."'”
Samuel Rutherford ní bíi ọ̀ọ́dúnrún ọdún lẹyìn ìgbà náà kọ̀wé pé, “Bí ìfẹ́ Krístì ti rí kò yé mi. Bí mo bá mọ̀ ohun tí Ó ní ní'pamọ́ fún mi ni, mi ò níí rẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀.”
Ṣé o gbà bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́ yìí? Ó máa ń nira fún wa láti gba ìfẹ́ yìí, a maá ń lérò pé a kò yẹ, a kò ṣeé fẹ́, tàbí a kò yẹ l'ẹ́ni ìtẹ́wọ́gbà. A ní èrò tó jinlẹ̀ nínú ẹ̀mí wa pé a sì ń kùnà. Ṣùgbọ́n bí a bá kùnà bẹ́ẹ̀, a ó pàdánù ọ̀pọ̀ nínú ìbùkún àti àǹfààní tí Ó ní fún wa nísinsìnyí àti ní ọjọ́ iwájú.

Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ yìí làti Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend ṣe àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ìfẹ́ ní ìlànà Bíbélì àti bí a ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.thistlebendministries.org