Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?Àpẹrẹ
Ìdáhùn wa si ìhìnrere kà Éfésù 2:1-10, Éfésù 1:1-15, àti 3:14-21. láìka bí a se mò tàbí jé àjèjì si ìhín rere tó, ka ìṣúra re ki o si fi ṣe àṣàrò tàdúràtàdúrà lórí ihìnrere. A ti mú àwọn m Ìwé Mímọ́ ati esè Bíbélì kíkà láti ràn e lówó pèlú èyí. So fún Olúwa Ki o tàn ìmólé ìhìn rere sínú ọkàn ẹ pèlú àgbàrá oníjèléńké. A fẹ́ rí Jésù àti ìrúbọ E kí a rí ọkàn wa àti ara wa bí Olórun ri won. A kò fẹ́ itànjé. Ìhìn rere kìí ṣe eré ìmárale ìmò èyíkéyìí lásán; O jé ohun ọkàn. Ṣàgbéyẹ̀wò agbára ìhìn rere nínú ayé ati ipá e lórí e. Máa se èyí fún ọjọ́ mélòó. Ki o si wò kàlẹ́ńdà ki o sàmì si ọjọ́ àti àkókò, ọ̀sẹ̀ kan sígbàyi, ti o ba lo ìṣẹ́jú 15-20 ni ìdùpe lówó Olórun àti ṣòjòyo gbogbo ohun tó se láyé e nípasẹ̀ ìhìn rere. Bi o ń se àṣàrò lórí ìhìnrere, rí dájú pé ó jẹ́ aláìlábòsí pèlú ará e àti jé kí okan hàn si Olúwa. Sò fún ibi tí o ti ni ìyèméjì, ìbéèrè,ìdángunlá, ọkàn to lè koko, ìmọ̀lára àìbìkítà, tàbí àìni igbàgbọ́ nínú ohunkóhun. Kò sí ohun láti bẹ̀rù nìgbà ti a báwa nínú Kristi. O ṣèlérí fún wa pe ti a. A jé jéwo àìṣèdédé wa, Olódodo ni Olórun láti dárí jì wa (1 Jòhánù 1:9).
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ yìí làti Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend ṣe àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ìfẹ́ ní ìlànà Bíbélì àti bí a ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.thistlebendministries.org