Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?Àpẹrẹ
A Kò Le Ṣe Ayédèrú Ìfẹ́ Tòótọ́
Ìfẹ́ tòótọ́ wà láàrin gbùngbùn īhìnrere, ìhìnrere sì jẹ́ ìfarahàn ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìhìnrere ni ìṣe ìfẹ́ tó ga jùlọ. Nípa ìhìnrere nìkan ni a ti rí ìfẹ́ tòótọ́ gbà. A tí fún wa ní agbára láti mọ ìfẹ́ tòótọ́, gbádùn ìfẹ́ tòótọ́, gbé nínú ìfẹ́ tòótọ́, fúnni ní ìfẹ́ tòótọ́ nínú Krístì.
Kíni Ìhìnrere?
Ìhìnrere ni ìròyìn ayò pé ẹnìkan ti gba ẹ̀bi àti ìjìyà tó tọ́ sí wà fún gbogbo àìṣedéédé wá sí Ọlọ́run. Kíni ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀? Ikú, ìbínú Ọlọ́run, oró ayérayé àti ìyapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀run àpáàdì. Jésù, ẹnìkan ṣoṣo tó lè san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa, ó gbáradì, gba ipò wa, Ó sì gba GBOGBO ìjìyà tí ó tọ́ sí wa. Jésù, ẹni pípé, aláìlẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run ní kíkún àti ènìyàn ní kíkún, fi ẹ̀mí Rẹ̀ sílẹ̀ fún wa. Òun tó wà láìlẹ́ṣẹ ru GBOGBO ẹ̀ṣẹ̀ wa, GBOGBO àìníláárí wa, àti GBOGBO àṣìṣe wa ṣ'ára Òun tìkararẹ̀ rọ́pò èyí Ó fún wa ní ìwà-mímọ́ Rẹ̀, àbùdá Rẹ̀, àti ÒDODO Rẹ̀.
Ẹni tí ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ lé'lẹ̀ fẹ́ kí o mọ irú ìfẹ́ yìí, kí o gbà á, ní ìrírí rẹ̀, gbé inú rẹ́, kí o sì fífún elòmíràn.
Ṣé o ti gba irú ìfẹ́ yìí? Tí kò bá dá ọ l'ójú, a pè ọ́ kí o ka "Ìhìnrere Ìgbàlà Wa." Bí o bá mọ̀ pé o ti gba ìdáríjì Ọlọrun tí o sì f'ọkàn tán Krístì àti ìfẹ́ Rẹ̀, ohun tó kàn tí a fẹ́ kí o ṣe báyìí ni kí o gbàdúrà kúkurú yìí kí o tó tẹ̀síwájú: “Olúwa mo bèèrè pé kí O sí mi l'étí láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ, sí mi l'ójú láti rí Ọ àti òtítọ́ Rẹ, sí ọkàn mi láti dáhùn sí gbogbo ohun tí O fi hàn mí. Ràn mí lọ́wọ́ láti ní òye àti láti gba ìfẹ́ tòótọ́ Rẹ kí n sì lè ní ìmọ̀ síi nípa ohun tí o ti ṣe fún mi ati kí n lè gbé nínú ìfẹ́ tòótọ Rẹ. Àmín.”
Ìfẹ́ Ọlọ́run fún ọ ní olúborí ìfẹ́. Níní òye, gbígbà àti níní ìgbàgbọ́ nínú ìfẹ́ tòótọ Rẹ̀ ṣe pàtàkì ó sì jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ẹni tí a jẹ́, ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Krístì, àti gbogbo ohun tí à ń ṣe ní gbogbo agbọn ayé wa. A sì ní láti rìn nínú ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa lẹ́sẹẹṣẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ yìí làti Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend ṣe àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ìfẹ́ ní ìlànà Bíbélì àti bí a ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.
More