Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?Àpẹrẹ
Ìlépa Tó Ṣe Pàtàkì Jùlọ
Tí ìfẹ́ òtítọ́ bá jẹ́ ìlépa tó gbomi jù lọ́kàn wa ní tòótọ́, ó dá mi lójú wípé a ma fẹ́ mọ bí ó ti rí àti bí a ṣe lè ríi gbà. Ìbéèrè náà lè la ọkàn wa kọjá, bóyá a tilẹ̀ lè dá ìfẹ́ òtítọ́ mọ̀?
Tí Ọlọ́run bá jẹ́ ìfẹ́,
tí Ọlọ́run sì paá láṣẹ fún wa láti fẹ́ràn Òhun,
tí Ọlọ́run, nípa ore ọ̀fẹ́, ti bu omi ìfẹ́ Rẹ̀ rin ọkàn wa nípasẹ̀ ìgbàlà ti Kristi,
nígbà náà ni a lè fèsì wípé bẹ́ẹ̀ni—láìsí àní-àní BẸ́Ẹ̀NI!
A ti fún wa ní agbára láti mọ ìfẹ́ òtítọ́, jẹ̀gbádùn ìfẹ́ òtítọ́, gbé nínú ìfẹ́ òtítọ́, àti láti fi ìfẹ́ òtítọ́ hàn. Tí Ọlọ́run tìkára rẹ̀ bá jẹ́ ìfẹ́, kìíṣe àpẹrẹ àti gbèdéke ìfẹ́ lásán fún wa, àmọ́ orísun rẹ̀ gan-an ni ó jẹ́ pẹ̀lú.
Àmọ́ ǹjẹ́ ìdíwọ́ wà tó lè díwa lọ́nà bí?
Àìgbàgbọ́? Ìpalára? Dídani? Àìgbẹkẹ̀lé? Àìní-ìwúrí? Iṣẹ́? Ilé-Ìgbé? Gbajúmọ̀? Ìbẹ̀rù? Àìyẹ? Ìkùnà? Ro àwọn ǹkan yìí dáadáa lónìí bí o ti ń ṣiṣẹ́, wà nílé, wa ọkọ̀ . . . lẹ́yìn rẹ̀ kí o wá tọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà kí o sì ṣàlàyé ǹkan tí o bá rí. Tí o bá lérò wípé kò sí ìdíwọ́ kankan lọ́nà rẹ, síbẹ̀ o ṣì ń tiraka láti gbé ìwọ̀n nínú ìfẹ́, sọ èyí pẹ̀lú fún Ọlọ́run.

Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ yìí làti Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend ṣe àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ìfẹ́ ní ìlànà Bíbélì àti bí a ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.thistlebendministries.org