Bò Nínú Àjàgà Ìfarawéra Ẹ̀kọ́-Àṣàrò Ọlọ́jọ́ Méje Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ

Break Free From Comparison a 7 Day Devotional by Anna Light

Ọjọ́ 1 nínú 7

O nìdí tí o fí yàn ètò kíkà yìí.

Bóyá o ń tiraka lábẹ́ ìtẹ̀wọ̀n ẹ̀rù ìfarawéra lémọ́lémọ́, tí o sì nfí ìgbàgbogbo kùnà sí ìdiwọ̀n tó ṣòro lọkàn rẹ. Bóyá o tí pàdánù ìbásépọ̀ ọ̀rẹ́ nítorí ìfẹ àti jẹ́ ẹ̀ni tó dára jùlọ, tàbí àwọn ìbásépọ̀ rẹ tí kùnọ̀ ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ nítorí ìfarawéra tí jà ọ l'óle àti jẹ́ ọ̀rẹ́ òtító tó ngbé nìí ga.

Bóyá o kàn tí su ọ.

O rẹ̀ ọkàn lori lémọ́lémọ́ rògbòdìyàn ayé tó mú ọkàn kún fún àníyàn, íyèméji, ìrẹ̀wẹ̀sì ati ìbínú nítorí ìfarawéra.

“Mí ò lé ṣ'éyi mọ́!” ní ó lérò. O ńfẹ́ ibi àlàáfíà tí a tí lè féràn rẹ nítorí ẹdà tí o jẹ́, kìí ṣe fún ohun ìní rẹ, àṣeyọrí rẹ, òkìkí rẹ̀, ipá rẹ̀, àti àwọn tó fẹ́ràn rẹ. Ìfẹ́ tí o lábawọ́n.

Mo mọ̀, nítorí èmi nìyẹn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, mo pínnu láti gbà àwẹ̀ olómi nìkan tí ọlọ́jọ́ méta, láti gbàdúrà lórí ohún mélo kàn tí mo fẹ́ borí nínú ayé mí. Mo kọ ádùrá mélo kàn sínú ìwé pélébé mo sì lẹ̀ sára ògiri iyàrá mi. Mo já fáfá láti máa tètè jí láàrọ̀ kùtù kí nlo àkókò díẹ níwájú Ọlọ́run láti gbàdúrà lórí ìwé pélébé wọ̀nyí… fún bíì ọ̀jọ́ méta. Kété tí àwẹ̀ mí parí, àsìkò àfikún ádùrá mi náà fẹ dàbí ẹni fẹ́ parí bákanná. Ohún tí kò tán ní agbára Ọlọ́run tí ńṣiṣẹ́ nínú ayé mi nípasẹ àwọn ádùrá tó ṣe pàtó tí mo gbe kalẹ̀ sí ẹsẹ́ Rẹ.

Ádùrá kan pàtó ní pé: “Ràn mí lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí ìfarawéra!” O jọ̀ pé a fà mi kùlẹ̀, pé ẹrù àìrí borí mi, mo fọ́ju nídi iṣedajọ́ mí sí ẹlòmíràn. Mo yẹra lórí ìkànnì àjọlò fún àwọn tó mú mi nímòlárà pé mí o tó ojúwọ̀n. Mo sọ̀rọ̀ àìdá nípa àwọn èèyàn tí mo ńjowú àti pé mí ò sí ṣàjọ́yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó nṣiṣẹ́ ohun nlá nínú ayé wọn. Àlàáfíà kan ṣoṣo tí mò ni nì ìyàraẹniṣọtọ. Nígbàtí kò sí ẹ̀nikan mọ́ láti fí ará mi wé, mo wá láiléwu. Ṣugbọ́n ìdánìkanwà wa wọ̀le o mú àgbayé mi kéré àti pé ọkàn mí sí kéré síi pẹlú. Mo fẹ́ ọ̀nà ÀBÁYỌ!

Ètò kíkà yìí ní ìdáhùn tí mo ní ìmọ̀lára pé o wá tààrà láti orí Ìtẹ́ Òòrè Ọfẹ. Ní ọ̀jọ́ méje tó mbọ̀ yi a máa ṣàwarí àwọn ìbéèrè bí:

Kíni ìfarawéra?

Kí ló má ṣẹlẹ̀ tí a bá ṣe ìfarawéra?

Báwó ní a ṣe lè borí ìfarawéra?

Nípasẹ àwọn èrò wọ̀nyìí, tí à fún mi tààrà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lórí ìṣewádìí ádùrá mi fún òmìnira, mo nígbàgbọ̀ wípé ìwo náà yíò ri òmìnira lọ́wọ́ pàkúté ìfarawéra pẹlú ìrírí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti ìgbé ayé ọ̀pọ̀ tí O ṣètò fún ọ.

Olúwa, ó rẹ̀ mí gán. Ó sú mi láti má ní ìmọ̀lárá nígbà gbógbó pé mí kò tó íwọ̀n, mí ò ṣe tó, mi o ṣàṣeyọrí tó. Ayé àyíká mi fún mi ní anfààní tó pọjù láti fi ara mi wé ẹ̀lomíràn mo sì mọ̀ wípé kò dára. Ràn mí lọ́wọ́ láti gb'éyi kalẹ̀ sí ẹ́sẹ̀ Yín pẹ̀lú ìdánilójú kíkún wipé mo lè ní òmìnira kúrò ninú èyí. Mo fẹ́ jẹ́ ẹnití Ẹ ṣẹ̀dá tí kò sí ohunkóhun tí yió fà mi sẹ̀hìn láti le tọ́ ìpá òhún tó ṣèéṣe fún mi lẹ́kùnrẹ́rẹ́, ní Orúkọ Jésù'.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Break Free From Comparison a 7 Day Devotional by Anna Light

Ìwọ́ mọ̀ wípé Ọlọ́rùn pèsè ìgbé ayé ọpọ yantúrú jú èyí tó ń gbé yì lọ, àmọ́ òtítọ́ tó kóro ní wípé ṣíṣe ìfáráwéra fà ọ sẹ́yìn láti lọ sí ipélé tó kan. Nínú ètò kíkà yìí Anna Light hú àwọn ìjìnlẹ̀ òye jáde láti fọ́ àpótí tí ìfáráwéra fi dé àwọ́n àbùdá rẹ, àti ràn ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé òmìnira oún ìgbé ayé ọ́pọ yantúrú tí Ọlọ́rùn tí yà sọ́tọ fún ọ

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Anna Light (LiveLaughLight) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ lọ sí: http://www.livelaughlight.com