Bò Nínú Àjàgà Ìfarawéra Ẹ̀kọ́-Àṣàrò Ọlọ́jọ́ Méje Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ
Kíni À Ńpè Ní Ìfáráwéra?
Ìfáráwéra jẹ́ irúfẹ́ tàbí ìfarahàn àìdáraẹ́nilójú. Ó máa njẹyọ láti inú àìní. Àìní ìmọ̀ ẹni tí a jẹ́. Àìní ìmọ̀ ohún tí a pè wá láti ṣe. Aìní ìgboyà nínú ẹni tí a jẹ́ àti irú ìgbésíayé tí a fi fún wa.
Àìdáraẹnilójú má ńwáyé nígbàtí a bá gbà irọ́ gbọ́ láìmọ̀ tàbí láì ní ìgbàgbọ́ nínù eni tí a jẹ́. Nítorina nígbàtí a bá ńfi àra wa wé ẹlòmíràn, ohún tí à ńsọ ní pàtó ni wípé, " Mi ò mọ̀ tàbí gbàgbọ́ nínú ẹni tí mó jẹ́, àti wípé mi ò mọ̀ tàbí gbàgbọ́ nínú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.”
A ńṣe ìfarawéra nítorí à ńwá ohun tí a lè fọkàntẹ̀ yàtọ̀ sí ara wa. Bóyá a mọ̀ tàbí a kò mọ,̀ a máa ńwá gbèdéke ibi tí a gbéwọ̀n dé nínú ayé. A máa ńfẹ́ mọ dèédé àyè wa nínú ayé, ibi tí a kù sí àti bí a ṣe ṣe déédéé sí pẹlú ẹlòmíràn nítorípé a ṣàìní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó jẹ́ tí àtinúwá.
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nínú wa máa ńṣe ìfarawéra nítorí a kò ní ìgboyà. Àwọn tí ó ní ìṣòro ìfarawéra lé mà mọ̀ bí a ṣe bukun wọn tó, fi àwọn àmúyẹ gidi jíǹkí wọn tó nítorípé àfojúsùn wọn lori ẹlòmíràn lò dá lé. Ọ̀pọ̀ àwọn míràn má ńṣe ìfarawéra nítorípé àbùdá ìṣẹ̀dá wọn jẹ́ eyi tíì má ńfẹ fi ìgbà gbógbó f'igagbága tàbí jẹ́ kí óhún gbógbó gún régérégé. Èyí jẹ́ ìṣẹ̀dá awọn tí ó ní àbùdá Type-A. Ò má ń sábà jáfafa nínú ohun gbogbo, adarí tí àwọn ènìyàn ńwárí fún ni ọ, èkàn ọkùnrin tàbí obìnrin láwùjọ rẹ́, nítorí ìdí èyí, èrèdí àti ṣe ìfarawéra má ńwa láti ara pé wọ́n nífẹ̀ kí wọ́n ma jẹ́ orí ní gbógbó ìgbà. Jíjẹ́ ẹni tí o tayọ jù máa ńmu kí ènìyàn dá'ra ẹni lójú, àmọ́ irúfẹ́ ìdáraẹnilójú yí kìí t'ọ́jọ́. Ohunkóhun tó lé mú ká ma fíra wéra, a ní láti mọ̀ dájú pé ṣíṣe ìfáráwéra yi kìí mú ìrẹ̀lẹ̀ tòótọ́ wa, irú èyí tó wu Ọlọrun.
Ìfarawéra tún jẹ́ olè. O ti gbọ́ bí a ti ńwípé "Ìfarawéra máa ńpa ìtẹ́lọ́rùn." "Ìfarawéra jẹ olè ti ńjí ayọ̀." "Ìfarawéra ńpa ípá rere rẹ.”
Ìfarawéra ńja olè, ó sí ńpa ọkàn àti ẹ̀mí wa run. Nítorí ìdí èyí, a rí ìfarawéra gẹ́gẹ́ bíi irin-iṣẹ́ ọ̀tá. Ọ̀tá rẹ kórìra rẹ débi pé kò ní dẹ́kun láti ké ẹ̀mi Ọlọ́run kúrò nínú rẹ, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìyè tí Ọlọrun ṣèlérí fún ọ. Nígbàtí a bá fi ààyè sílẹ fún ìfarawéra, à fún ọ̀tá láàyè nínú ayé wa, a kò sí ní lè ní anfààní sí ohún gbógbó tí Ọlọ́run tí ṣe létò fún wa.
A lè má mọ̀ọ́mọ̀ ṣé ìfara wéra ṣùgbón ìtànjẹ àti ẹwù tó wà nínú ìfarawéra hàn gbangba sí wa nítorípé Ìfarawéra jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Sùgbọ́n bí tií rí pẹlú ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ, a ní láti fi ara wá jìn ìgbé-ayé tí kò ní ẹ̀ṣẹ tí ó sì jìnà sí ìfarawéra.
Njẹ́ o má ńṣe ìfarawéra nítorípé kò sí ìgboyà, tàbí nítorípé o lérò aabo-eké láti jẹ́ ẹnití ó tayọ jùlọ?
Olúwa, mo jẹ́wọ́ pé mo máa ńdígbàá ṣe ìfara wéra mi pẹ̀lú ẹlòmíràn. Mo má ńṣe bẹ́ nígbà míràn láìmọ̀. Mo fẹ́ mọ̀ Ọ́ dunjú mo sì fẹ́ mọ irú ẹni tí mojẹ́ nítorí Rẹ. Mo ṣ'àfẹ́rí ìgboyà àtinú wa èyí tí ó ti ìbáṣepọ̀ emi pẹ̀lú Rẹ jáde wá. Ṣe àwárí ọkàn mi ki O sí fi hàn mí ìdí tí mo fi ń tiraka lórí Ìfarawéra kí O sì dà mí n'ídè ní orúkọ Jésù!
Nípa Ìpèsè yìí
Ìwọ́ mọ̀ wípé Ọlọ́rùn pèsè ìgbé ayé ọpọ yantúrú jú èyí tó ń gbé yì lọ, àmọ́ òtítọ́ tó kóro ní wípé ṣíṣe ìfáráwéra fà ọ sẹ́yìn láti lọ sí ipélé tó kan. Nínú ètò kíkà yìí Anna Light hú àwọn ìjìnlẹ̀ òye jáde láti fọ́ àpótí tí ìfáráwéra fi dé àwọ́n àbùdá rẹ, àti ràn ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé òmìnira oún ìgbé ayé ọ́pọ yantúrú tí Ọlọ́rùn tí yà sọ́tọ fún ọ
More