Bò Nínú Àjàgà Ìfarawéra Ẹ̀kọ́-Àṣàrò Ọlọ́jọ́ Méje Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ
Ọ̀ná tí o rọrùn tó sì yára pani rún jùlọ ti a ma ń gba se ìfarawéra ni Ìkànnì Ìbánidọ́rẹ̀. Mo wípé o yára láti pani rún nítorí nkán méjì: a ma ń lo Ìkànnì Ìbánidọ́rẹ̀ lójoojúmọ́, kódà ni aimoye igba lóóòjọ́, púpọ̀ nínú àwọn àkókò yí ni à sì ma ń dá wà pẹ̀lú èrò wa. Òtítọ́ tó bani nínú jẹ́ ni wípé irú ǹkan bẹ́ kò sí ní ọdún mẹwàá sẹ́yìn. Níwọ̀n bí ọdún mẹwà sẹ́yìn, Ìkànnì Ìbánidọ́rẹ̀ gba gbógbó àṣà wa tí o sì ti ṣokùn fa àjàkálẹ̀ àrùn ọkàn tí o nfẹ́ àkíyèsí ṣùgbọ́n tí o dánikanwà jú tèṣi lọ.
Ohun tí a ṣe àpẹẹrẹ rẹ láti so wá pọ̀ tí bẹ̀rẹ̀ sí mú wá dánikanwà, bí a kò bá sì ṣọ́ra, èrò ápánírún ìfarawéra yi le mú ọkàn wa rọ́ kíákíá jú nkán míràn lọ.
Èíṣe?
Àpapọ̀ kíkà ènìyàn à máà ni Ìkànnì Ìbánidọ́rẹ̀ tó bí márùn-ún àti pé wọ́n a má lò tó bí wákàtí kàn lè ní ogójì iseju lójoojúmọ́ láti lọ káàkiri rẹ̀.
A sì má ṣe wá ní kàyéfì ìdí rẹ̀ tí a fi ńjà lórí ìfarawéra, àìpé, àìláàbò àti àìní wọ'ya.
Kíni à ńgbé sì ìwájú wa ni gbógbó ìgbà?
Síbẹ̀síbẹ̀, n kò lérò wípé idahun sì ìbéèrè yí ni kí á yọ̀ ara wa kúrò nínú Ìkànnì Ìbánidọ́rẹ̀. Èṣù ti lọ jìnà. A ní láti rántí wípé a wà nínú ayé bẹ́ sì ni a kìí ṣe tí ayé. A ní làti kọ́ lílo Ìkànnì Ìbánidọ́rẹ̀, bí a ti n kọ́ ohun míràn, fún ire wá, ati fún ogo Rẹ̀.
Irú ara ti a ní ati ìrìnísí wá jẹ́ ìfarawéra tí a tún máà ńṣe ní kíákíá. A lè wo enìkan kí a sì fi ìrísí kan yẹn ṣé ìdájọ́ àti afiwe látàrí bí wọn ṣe múra, ìfipajú wọn, irun wọn tàbí bí wọ́n tí n gbe ara wọn. Nígbà miran o máa n jẹ́ àkíyèsí kéékèèké àwọn ènìyàn tí n wo wá kò sì sí ohùn tí o burú nínú èyí. Ìṣòro to wà níbẹ̀ a máà jẹ yọ nígbà tí a bá ńṣe àṣìṣe àti máà fi ara wa wé ẹlòmíì látàrí ìrínisí wọn.
Ìgbàmíràn ẹ̀wẹ́ ìfarawéra máà ń wá ní irúfé ohun ìní ayé bí ilé, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, owó oṣù ati asiko ìsinmi. A nri ìta, agolo, ààmì, orúkọ ọjà àti aṣọ ilé, a sì n ṣe ìdájọ́ ni kíákíá lai mọ gbógbó ìtàn náà délẹ̀. Ìṣòro tó wà nínú èyí a máà jẹyọ nígbà tí a bá n pá ara wa mọ́ kúrò nínú fifi òtítọ́ ni ìbáṣepọ̀ pelu awon ẹlòmíràn. A má n lérò wípé a ò jọ sí nínú ẹgbẹ́ kan náà tàbí pé kò sí ohun tí wọ́n lé fún wa nítorí iwòye tí a ní sì wọn.
A tún ma ń fi ìrírí ayé àti àṣeyọrí ẹlòmíràn wé tiwa. O fẹ́ ni ọkọ tàbí aya, ṣùgbọ́n o ṣí wá ní àpọ́n. Ò n woju Olúwa fún ọmọ tàbí o n fẹ́ àsìkò ìdakẹrọ́rọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ rẹ́! Ẹ̀bí tí kò wá ní alailoye wún ọ. O ni ara tó rẹwà, ìwọ ṣì nwa bí o ti fẹ́ sọ ọ̀rá ọmọ bibi tí o ti n gbe kiri fún ọdún márùn. Ibi ìṣẹ́ rẹ̀ rúwé, tìrẹ fìdírẹmi.
Ohún tí a fi n wé ra a máa fi ohun tí o jẹ wá lógún púpọ̀ hàn. N' ó jiyàn wípé kí a má kàn pá ojú ìfarawéra àti òwú de. Mo ti kọ́ wípé a lè lo wọ́n gẹ́gẹ́ bi irinṣẹ́ fún títọ́ pasẹ̀ ayé wa ati fún títàn ìmọ́lẹ̀ sì àti mọ ara ẹni. A o sọ̀rọ̀ síwájú sí lórí èyí lọ́la.
Olúwa, ṣí ojú mi sì awon òhún ti o má mú mi ni ìmọ̀lara òró-òwú. Rán mi lọ́wọ́ láti yí jígí sí ojú mi ki n lè ní àkókò àròjinlẹ̀ lórí ohun tí mo nfi àkókò mi ṣe. Fi hàn mí ìdí tí mo fi n ni ìfòyà àwọn ènìyàn tàbí àyídáyidà kí o sì rán mi lọ́wọ́ láti má gbé ara mi sókè tàbí sílẹ̀ ju ẹlòmíì látàrí ìdájọ́ mi lórí ìrínisí wọn.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìwọ́ mọ̀ wípé Ọlọ́rùn pèsè ìgbé ayé ọpọ yantúrú jú èyí tó ń gbé yì lọ, àmọ́ òtítọ́ tó kóro ní wípé ṣíṣe ìfáráwéra fà ọ sẹ́yìn láti lọ sí ipélé tó kan. Nínú ètò kíkà yìí Anna Light hú àwọn ìjìnlẹ̀ òye jáde láti fọ́ àpótí tí ìfáráwéra fi dé àwọ́n àbùdá rẹ, àti ràn ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé òmìnira oún ìgbé ayé ọ́pọ yantúrú tí Ọlọ́rùn tí yà sọ́tọ fún ọ
More