Bò Nínú Àjàgà Ìfarawéra Ẹ̀kọ́-Àṣàrò Ọlọ́jọ́ Méje Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ

Break Free From Comparison a 7 Day Devotional by Anna Light

Ọjọ́ 7 nínú 7

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ètò wa, a ríi wípé àìní ni ìpìlẹ̀ ìfarawéra. Àìní òye ẹ̀ní tí Ọlọ́run jẹ́, àti tani àwa jẹ́ nítorí tíRẹ̀. 

Ó dá mi lójú wípé aìle wà ni àjọṣe pẹ̀lú Rẹ̀ lójojúmọ́ ní ṣé pẹ̀lú àìní òye tó péyé lóríi àbùdá Rẹ̀ ni tòótọ́. Kìí ṣé oníbínú abáyọ̀jẹ́, tó ńwò wá láti ọ̀rún ní ìrètí àṣìṣe wá. Kò díwọ́. Kò dá wa lẹ́bí, dá wa lẹ́jọ, tàbí kí ó ní ìmọ̀lára tó lòdì sí wa. Ó mọ̀ni jinlẹ̀, Ọlọ́rùn ìfẹ́, tí Ó súnmọ wa bí ìlù ookan-àyà wa.

Ó sí pé péerépé. Kò ní àìní kánkan. Ìṣẹ́ tí Jésù ṣe lórí àgbélébùú gbà wá láàyè kí Ẹ̀mí Ọlọ́run lé gbé inú wa. Nítoríná, awá pàápàá ò ní àìní kánkan.

Tí ó bá dé ibi ìfarawéra, a kàn ní láti rántí: ẹ̀nikọ́ọ̀kan wa jẹ́ ìfihàn àbùdá Ọlọ́run—abala ìṣẹ̀dá Rẹ̀ ti Ó fẹ́ kí ayé mọ̀. 

Ǹjẹ́ o mọ́ ábálá tí Ọlọ́run nfi hàn nípásẹ̀ rẹ?

Ǹjẹ́ ìwó jẹ́: 

Elétò, Aláàánú, Amojúṣe, Ẹni-tó-lójú-ọnà, Ẹni-tí-ọkàn-rẹ-fuyẹ, Ẹni-tó-kó-ara-ní-ìjánu, Aláànú, Apanilẹ́rin, Eni-tó-já-fáfá, Kò-gba-gbẹrẹ, Adákẹ́-rọrọ, Af'ara-balẹ̀-gbọ́ràn, Olùtọ́jú, Alá-figa-gbága, Aláìní-aápọn, Onítara…Ó ti fi àbùdá Òun tìkara Rẹ̀ kan sínú rẹ. Ọlọ́run Nfi ojú hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà! Ó nílò gbogbo ẹ̀dá énìyàn láti ṣàlàyé Ẹni tí Òun jẹ́ sí wa!

Mí mọ ẹni tí ìwọ́ jẹ́ àti àwọn àbùdá tí ó ta ọ yọ, èyítí Ọlọ́run fi fún ọ, yíò fún ọ ní ìgboyà láti ṣe ohún tí ó yẹ nígbàtí o bá ní ìdánwò áti ṣàfiwé. Bèrè lọ́wọ́ ará rẹ, “Kíni ẹni yìí ń fi hàn mí nípa Ọlọ́rùn?” 

Nípa àwọn nkan tí wọ́n fí ṣọwọ́ káàkiri lórí pèpéle-ìkàn-s'àwùjọ béèrè, “Agbọndán Ọlọ́run wo ni mo lè rí nínú ẹni yìí?” 

Nínú àjọṣe pọ̀ pẹ̀lú àwọn míràn, “Kíni ohun tí Ọlọ́rùn nfí hàn mí nípa àjọ́ṣepọ̀ yí?” 

Nígbàtí ẹ̀bùn tàbí àṣeyọrí ẹlòmíràn bá fẹjú mọ́ ọ, “Báwo ni mo ṣe lè ṣé ajọ́yọ̀ ohun tí Ọlọ́run ńṣe nínú ayé ẹni náà?” 

Nígbàtí ìwọ́ bá gòkè siwaju sì nínú idáràẹnímọ̀ oún ìdánilójú ẹ̀dá tí Ọlọ́run yà ọ̀, kò kàn ní yá ọ l'árà latí ró èrò tó gbọ́wọ́ sókè nìkán ṣugbọn òó lé sọ́ jáde síta pẹlu. Ìwọ yíó lè máa gbóríyìn pẹ̀lú ọkàn tó já gáará lati máa ṣé ìgbénisókè dípò àti ṣe ifánisílẹ ẹlòmíràn tàbí ara rẹ́ nitori ìfáráwéra. Ìwọ yíó sí di ẹni ìsọ́nídàayè sí ẹlòmíràn! 

Bí o ṣe ń rí ara rẹ bí ọ̀kan-pàtàkì nínú àbùdá Ọlọ́run, oó wà bẹ̀rẹ̀ sí ní rí àwọn ènìyàn yókù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ní gbẹ̀yìn, oó lè borí pánpẹ ìfáráwéra. 

Òlúwa, ràn mí lọ́wọ́ láti rí ára mi gégé bí Ò tí nrí mí. Là mí lójú lati ri Ọlọrun nínú ẹní kaakan tí mò bá ṣe àlábàpàde kí ibaṣepọ̀ mi lè gbé ògo fún Ọ. Mo gbàdúrà kí O ṣé àfihàn ìníyelórí mi àti àbùdá Rẹ tí ó tayọ tí O ti fi sí inú mi kí ń ba lè yọ́ ayọ̀ àwọn irúfẹ́ àbùdá Rẹ tí O fí sínú àwọn ẹlòmíràn. Mi ò ní ṣe ìfarawéra mọ́. Mo tún sọ léèkan si, mi ó ní fi ara mi wé ẹlòmíràn mọ́, ṣùgbọ́n màá ṣe ipa mi láti ṣe ajọ́yọ̀ ara Kristì kí ó bá lè di kíkọ sókè àti kí ó gba agbára, ní orúkọ ńlá Jésù tí ó lágbára, Àmín!

Mo lérò pé o gbádùn ètò kíkà yí. Fún àwọn ìrànlọ́wọ́ tó tún wúlò láti ṣẹ́gun àwọn ohún tó ń fani sẹ́yìn, bẹ Anna wò ní

Dàpọ̀ mọ́ Anna lórí Instagram: @annalight09

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Break Free From Comparison a 7 Day Devotional by Anna Light

Ìwọ́ mọ̀ wípé Ọlọ́rùn pèsè ìgbé ayé ọpọ yantúrú jú èyí tó ń gbé yì lọ, àmọ́ òtítọ́ tó kóro ní wípé ṣíṣe ìfáráwéra fà ọ sẹ́yìn láti lọ sí ipélé tó kan. Nínú ètò kíkà yìí Anna Light hú àwọn ìjìnlẹ̀ òye jáde láti fọ́ àpótí tí ìfáráwéra fi dé àwọ́n àbùdá rẹ, àti ràn ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé òmìnira oún ìgbé ayé ọ́pọ yantúrú tí Ọlọ́rùn tí yà sọ́tọ fún ọ

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Anna Light (LiveLaughLight) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ lọ sí: http://www.livelaughlight.com