Bibeli Fun Awon OmodeÀpẹrẹ
Noa je okunrin ti o sin Olorun. Gbogbo eniyan korira won si saigboran si Olorun. Li ojo kan, Olorun so ohun kan toje iyanu. “Emi yio pa aiye ese yi run,” Olorun wi fun Noa. “Idile re nikan ni yio gbala.”
Olorun kilo fun Noa wipe omi yio wa bo Ile aiye mole. “Ko oko ti afi igi se, oko nla ti yio gba idile re ati opolopo eranko,” Apase fun Noa. Olorun fun Noa ni eto lati ko oko na. Noa sib ere ise!
Awon eniyan fi Noa se efe nigbati o so idi re ti afi nko oko na. Sugbon Noa nko oko na. O kede Olorun fun awon eniyan. Kosi eniti o gbo.
Noa li igbagbo nla. Ogba Olorun gbo botile je wipe ojo kotii ro ri. Laipe ako awon ohun ti afe sinu oko na.
Awon eranko wa. Olorun mu awom miiran meje, awon miiran meji. Eiye nla ati kekere, awon oniruru eranko igbe.
Boya awon eniyan kigbe le Noa bi oti nko awon eranko wonu oko. Won ko dekun lati maa se si olorun. Won ko wonu oko.
Paripari, gbogbo eranko ati eiye oju orun wonnu oko. “Wa sinu oko,” Olorun pe Noa. “Iwo ati Idile re.” Noa, aya re, omokunrinre meta, ati awon aya won wonnu oko. Olorun ti ilekun oko na!
Nigbana li ojo bere. Ojo ro fun ogoji ojo ati oru.
Agbara-omi kun gbogbo Ilu ati igberiko. Nigbati ojo dawo duro, awon oke nla pelu wa labe omi. Gbogbo ohun toni eemi ninu salaisi.
Bi omi se goke si beni oko na goke si, oko na wa lori omi. Oko na le sokunkun ninu abi je ibi eru. Sugbon oko na da abo bo Noa lowo ikun omi.
Lehin osu mefa ikun omi, Olorun fi afefe ranse. Laipe ojo, oko na wa simi sori oke Ararati. Noa farapamo sinu oko fun ogoji ojo si bi omi na se fa kuro nile.
Noa fi eiye Iwo ati adaba ranse jade gba oju ferese oko. Lai ri ibi isimi eiye Adaba pada sinu oko.
Lehin ose kan, Noa tun se abewo. Eiye Adaba pada wa sinu oko pelu ewe olifi lenu re. Li ose to tele Noa mo wipe Ile aiye ti gbe fun omi nitoripe eiye Adaba ko pada wa sinu oko.
Olorun wi fun Noa wipe asiko tito lati fi oko sile. Lapapo, Noa ati idile re gbe awon eranko jade ninu oko.
Inu Noa dun repete! Osi te pepe, osi sin Olorun ti o gba ohun ati idile kuro lowo ikun omi.
Olorun se ileri iyanu fun Noa. Wipe ohun ki yio fi ikun-omi dajo ese eniyan mo. Olorun fi ohun iranti ileri re han. Ami osumare ni ami ti Olorun fi se ileri.
Noa ati idile re bere aye otun lehin ikun-omi. Laipe ojo awon iran Noa kun ori ile aiye. Gbogbo orile ede aiye ti odo Noa jade wa.
Opin
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bawo ni gbogbo rẹ ṣe bẹrẹ? Nibo ni a ti wa? Kini idi ti irora pupọ wa ni agbaye? Ṣe ireti eyikeyi wa? Njẹ aye wa lẹhin ikú? Wa awọn idahun bi o ti ka itan otitọ yii ti aiye.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Bibeli fun Awọn ọmọde, Inc. fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://bibleforchildren.org/languages/yoruba/stories.php