Bibeli Fun Awon OmodeÀpẹrẹ
Laye atijo, Olorun ran angeli Gabreli si omidan Israeli kan ti anpe ni Maria. Owifun pe, “iwo yio bi omokunrin kan, iwo yio sipe oruko re ni Jesu. Ao pee ni omo Olorun oga ogo. Yio si joba titi aye.”
“Bawo ni eyi yio se ribe?” Omobinrin na wi. “Emi ko tii mo Okunrin kan ri”. Angeli na so fun Maria wipe omo na yio ti odo Olorun wa. Ki yio ni Baba eleran-ara.
Angeli na so fun Maria wipe Elisabeti arabinrin re ti loyun ni ogbo ojo re. Iyanu ni eyi na je. Lehin eyi, Maria losi odo Elisabeti. Won yin Olorun papo.
Maria ni afesona ti a n pe ni Josefu. Inu Josefu ko dun nigbati o mo wipe Maria ti loyun. O ro wipe okunrin miiran lo fun loyun.
Ninu ala, Angeli Olorun so fun Josefu wipe omo na je omo Olorun. Josefu ni lati ran Maria lowo lati se itoju Jesu.
Josefu gbekele Olorun o si gboran si lenu. O tun gbo ofin ilu re. Nitori ofin titun, ohun ati Maria losi ilu betlihemu lati lo san owo ori.
Maria se tan lati bimo. Sugbon Josefu kori ile nibikibi. Gbogbo ile ipamo ni won ti gba tan.
Josefu pada wa ri ibuje-eran. Nibe, ni abi Jesu si. Iya re gbe si ibuje-eran nibiti awon eran ti njeun.
Nitosi, awon Oluso aguntan nso agbo eran won. Angeli Olorun farahan won osi fi ihinrere iyanu na fun won.
“Abi fun yin loni n’ilu Dafidi Olugbala ti ape ni Kristi Oluwa. E o ri omo na ti afi oja we odubule si ibuje-eran.”
Lojiji, opolopo Awon angeli alarabara farahan, won fi ogo fun Olorun wipe “Ogo fun Olorun ni oke ati aiye alafia, ife inu rere si gbogbo eniyan”.
Awon Oluso agutan losi ibuje-eran. Lehin igbati won ri omo na won so fun gbogbo eniyan ohun ti angeli na so fun won.
Lehin ogoji ojo, Josefu ati Maria gbe Jesu wa sinu tempili ni Jerusalemu. Okunrin kan wa ti ape ni Simeoni, fi iyin fun Olorun fun omo na nigbati Anna woli agba, osise Oluwa miiran dupe.
Won mo wipe Omo na je omo Olorun, Olugbala ti ase ileri re. Josefu fi eiye meji se irubo. Eyi ni irubo ti ofin Olorun so wipe ki won ose nigbati won ba gbe omo titun wa si odo Oluwa.
Lehin Igba kan, Irawo kan fi ona han awon okunrin ologbon lati ile ila-orun si Jerusalem. “Nibo ni omo na ti abi ni oba awon Ju wa?” Won beere. “Awa lati wa sin.”
Oba Herodu gbo nipa awon ologbon okunrin na. Okan re po ruru, o wi fun won pe ki won so fun ohun nigbati won bari Jesu. “Emi na pelu fe sin” Herodu wi. Sugbon eke ni eyi. Herodu fe pa Jesu.
Irawo mu awon Ologbon okunrin na losi ile ibi ti Maria ati Josefu ngbe pelu omo na. Won wole lati sin, awon aririn ajo na fi ebun fun Jesu, fadaka ati ohun oloorun didun.
Olorun so fun awon ologbon okunrin na lati pada sile loni bo nkele. Inu bi Herodu gidigidi. O pinu lati pa Jesu, eni ibi na pa gbogbo awon omokunrin ni Betlihemu.
Sugbon Herodu kolee se omo Olorun ni ibi! Pelu ikilo loju ala, Josefu gbe Maria ati Jesu losi Egipiti.
Nigbati Herodu ku, Josefu gbe Maria ati Jesu pada wa lati Egipiti. Won gbe nilu kekere kan ti ape ni Nasareti, leti okun Galili.
Opin
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bawo ni gbogbo rẹ ṣe bẹrẹ? Nibo ni a ti wa? Kini idi ti irora pupọ wa ni agbaye? Ṣe ireti eyikeyi wa? Njẹ aye wa lẹhin ikú? Wa awọn idahun bi o ti ka itan otitọ yii ti aiye.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Bibeli fun Awọn ọmọde, Inc. fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://bibleforchildren.org/languages/yoruba/stories.php