Bibeli Fun Awon OmodeÀpẹrẹ
Arabinrin na duro si eti apata na, oju ekun re nwo iran buburu na. omo re nku lo. Iya na ni Maria, osi duro leti ibiti akan Jesu mo agbelebu.
Bawo ni gbogbo eyi se bere? Bawo ni Jesu se maa pari aye didara si aye itiju ni? Bawo ni Olorun se maa fi omo re sile lati ku sori igi agbelebu? Se Jesu o mo eniti ohun je ni? Tabi Olorun kose dada ni?
Rara o! Olorun se dada. Jesu ko se asise. Jesu mo wipe a o pa ohun lati owo awon eni ibi. Nigbati Jesu wa ni omode, Simeoni arugbo ti so fun Maria ohun ibi to nbo wa sele.
Ojo die ki ato pa Jesu, arabinrin kan wa lati wa da ororo iyebiye si ese Jesu. “O n da owo nu” awon omo ehin re wi. “Oti se ise rere” Jesu wi bayi. “O se eyi fun isinku mi”. Iru oro kayefi wo re!
Lehin eyi, Judasi, okan ninu omo ehin mejila, gba lati fi Jesu han fun awon alufa agba pelu ogbon wura.
Ni ajo irekoja awon Ju, Jesu je ounje igbehin pelu awon omo ehin re. o so ohun iyanu fun won nipa Olorun ati awon ileri re si awon to feran re. Jesu si fi akara ati omi fun won lati pin. Eyi ni lati ran won leti wipe Jesu fi ara ati eje re fun wa fun idariji ese.
Jesu si so fun awon omo ehin re wipe a o fi ohun han awon omo ehin re yio si fonka. “Emi ko ni salo”, Peteru wi bayi. “Ki akuko to ke, iwo yio komi sile leemeta,” Jesu wi.
Ni oru ojo na, Jesu lo lati gbadura ninu ogba Getsimani. Awon omo ehin re ti owa lodo re sun lo fonfon. “Baba a mi”, Jesu gbadura, “… Jeki ago yi re koja lori mi, sugbon kiise bi mo tife, Ife re ni ko se.”
Lojiji, opo ero wonu ogba, Judasi lo siwaju won. Jesu ko ja, sugbon Peteru ge eti okunrin kan sile. Lai pariwo, Jesu fi owo kan eti arakunrin na osi wo san. Jesu mo wipe ki amu ohun je lara ero olorun fun ohun.
Awon eyi mu Jesu lo si ile Alufa agba. Nibe, awon agba Ju so wipe ki Jesu ku. Nitosi, Peteru duro leba ina awon eru osi nworan. Leemeta ni awon eniyan wo Peteru won si wipe “Iwo wa pelu Jesu!” Leemeta Peteru ko eyi, gegbi Jesu se wi. Peteru gegun o si bura.
Gele, akuko ke. O dabi ohun Olorun si Peteru. O ranti oro Jesu, Peteru sonkun kikoro.
Judasi pelu bara je. O mo wipe Jesu ko jebi ese Kankan. Judasi gbe ogbon wura pada sugbon awon alufa ki yio gba.
Judasi so owo na sile, o jade lo – o si pokun so.
Awon alufa mu Jesu to Pilatu wa, Gomina Romu. Pilatu so wipe, “Emi ko ri ese kan pelu okunrin yi.” Sugbon awon eniyan gbogbo wipe, “Kan mo agbelebu! Kan mo agbelebu!”
Nigbeyin, Pilatu gbo, osi pase ki akan Jesu mo igi agbelebu. Awon Omo-ogun gba Jesu lese, tu ito si loju, won si naa legba. Won de ade egun lee lori. Won si kan mo igi agbelebu lati ku.
Jesu mo wipe ohun yio ku iku oro yi. O si mo wipe iku re yio mu idariji ese wa fun awon to gbekele ohun. Ole meji ni akan pelu Jesu. Okan gbagbo – o losi paradise. Ekeji ko gbagbo.
Lehin ijiya pipe, Jesu wipe “o ti pari,” o si ku. Ise re ti pari. Awon ore re sin sinu isa oku titun.
Awon omo-ogun Romu so ibi iboji. Kosi eniti o le wole - tabi jade.
Bi eyi ba je opin itan yi, iba mu are wa. Sugbon Olorun se ohun ara kan. Jesu ko ku!
Ni kutukutu owuro ojo akoko ninu ose, awon omolehin Jesu kan ri iboji wipe osi sile. Nigbati won wo inu re, Jesu kosi nibe.
Arabinrin kan lo duro, o sonkun ni iboji. Jesu farahan! O sare loso fun awon omo ehin toku. “JESU WA LAAYE! JESU TI PADA WA LATI ISA OKU!”
Laipe, Jesu pada waba awon omo ehin re, o si fi owo re han won. Otito ni. JESU WA LAAYE SI! O DARIJI Peteru ti o ko sile, o si wi fun awon omo ehin re ki won so fun gbogbo eniyan nipa ohun. O si pada losi orun ti oti wa nigba keresimesi akoko.
Opin
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bawo ni gbogbo rẹ ṣe bẹrẹ? Nibo ni a ti wa? Kini idi ti irora pupọ wa ni agbaye? Ṣe ireti eyikeyi wa? Njẹ aye wa lẹhin ikú? Wa awọn idahun bi o ti ka itan otitọ yii ti aiye.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Bibeli fun Awọn ọmọde, Inc. fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://bibleforchildren.org/languages/yoruba/stories.php