Bibeli Fun Awon OmodeÀpẹrẹ
Nigbati Jesu gbe nile aiye o so nipa orun fun awon omo ehin re. o wipe “Ile BABA mi”, o wipe opolopo ibugbe nla lowa nibe. Ibugbe nla elewa. Orun tobi o si lewa ju ilekile ni aiye lo.
Jesu wipe, “Mo nlo lati pese aye sile fun yin. Bi emi balo pese aye sile fun yin, Emi yio pada wa lati gba yin sodo mi”. Jesu losi orun, lehin ti ojinde ni isa oku. Nigbati awon omo lehin re na wo, agba Jesu losi oke, ofurufu si gba kuro loju won.
Lati igba na, Awon Kristeni ti ranti ileri Jesu latipadawa mu wa. Jesu so wipe ohun yio pada de lojiji, nigbati ako reti. Sugbon bawo ni awon ti oku ki Jesu t’ode? Bibeli wipe won losi orun lati wa pelu Jesu. Lati ma wa ninu ara je wipe awa pelu Oluwa.
Ifihan, Iwe to kehin ninu Bibeli, so fun wa bi orun se dara to. Ohun to yani lenu ni wipe, ni ona to dara, orun ni ibugbe olorun. Olorun wa nibi gbogbo, sugbon orun ni ite e re.
Awon angeli ati awon eda alaye miiran nsin Olorun l’orun. Beni awon omo Olorun ti oti ku ti won sit i losi orun. Won nko orin iyin si Olorun.
Eyi ni okan ninu awon orin ti won nko: IWO L’OGO YE, NITORI OTI RA WA PADA FUN OLORUN NIPA EJE RE LATI INU GBOGBO EYA ATI ORILE-EDE O SI FI WA SE OBA ATI ALUFA SI OLORUN WA. (Iwe Ifihan ori karun ese kesan)
Iwe to kehin ninu Bibeli fi han wipe orun ni “Jerusalemu titun”. Otobi pupo, pelu ogiri titobi lode. Ogiri ilu na je jasipa, ti o mo daradara. Awon okuta meremere ni afi ko ogiri ilu na, ti o ntan pelu alarabara. Enu ona Kankan ti o wo ilu na ni afi pealii (okuta olowo iyebiye) se.
Awon enu ona peali yi ako nti won rara. Ejeki awole ki ase abewo re … AAA! Orun lewa ninu. Afi fadaka ko ilu na , bi awo jigi. Awon adugbo re ni afi fadaka se.
Elewa, omi ti o mo ti iye nsan lati inu ite Olorun. Leti odo mejeji na ni agbin igi iye si, ti akoko ri ninu ogba Edeni. Awon igi yi yato. O so orisi eso mejila, orisi eso kan ni osu kan. Ewe igi iye wa fun iwosan awon orileede.
Orun ko fe orun tabi osupa fun imole. Ogo Olorun fun ara re kun fun imole iyanu. Kosi oru nibe.
Awon eranko orun yato. Won je ohun ti ale fi sere. Ikoko ati eran agbo nje koriko papo. Awon kiniun nla nje koriko bi esin. OLUWA wipe, “won koni farapa tabi parun ni gbogbo oke mi”.
Bi ase wo yika, ari wipe a o ri awon ohun kan ni orun. A o gbo oro ibinu. Enikeni ko ja tabi se ahun. Ako fi kokoro si enu ilekun nitori wipe kosi ole ni orun. Kosi iro, apaniyan, eke, tabi awon eni ibi. Kosi ese kan ni orun.
Ni orun pelu Olorun kosi ekun mo. Nigba miiran awon eni Olorun nsonkun ni aye nitori aye yi. Ni orun Olorun yio nu gbogbo omije wa nu.
kosi iku ni orun rara. Awon eni Olorun yio wa pelu Oluwa titi lai. Kosi Ikoro mo, kosi ekun mo, kosi irora mo. Kosi aisan mo, kosi iyapa mo, kosi isinku mo. Gbogbo eniyan ni orun nyo pelu Olorun.
Parpari re, Orun wa fun awon omodekunrin ati awon omodebinrin. Ni orun iwe kan nbe ti anpe ni iwe iye odo agutan. O kun fun oruko awon eniyan. Nje o mo oruko awon towa nibe bi? Awon ti o gbekele Jesu. Se oruko o re wa nibe?
Oro igbehin Bibeli je oro ipeni. “Ati Emi ati Iyawo wi pe, ‘Wa!’ Jeki eniti o gbo so wipe ‘Wa!’ Jeki eniti ongbe ngbe wa. Ati eniti o fe, jeki omu omi iye l’ofe.”
Opin
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bawo ni gbogbo rẹ ṣe bẹrẹ? Nibo ni a ti wa? Kini idi ti irora pupọ wa ni agbaye? Ṣe ireti eyikeyi wa? Njẹ aye wa lẹhin ikú? Wa awọn idahun bi o ti ka itan otitọ yii ti aiye.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Bibeli fun Awọn ọmọde, Inc. fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://bibleforchildren.org/languages/yoruba/stories.php