Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú ÌgboyàÀpẹrẹ

Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú Ìgboyà

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ìgboyà láti wàásù

Ìsínjẹ kì í kàn ṣe ẹ̀yà ẹ̀tàn lásán ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ àwọn èrò ńlá máa ń gbà wá sí ìmúṣẹ. Nígbà tí a bá rí I tí àwọn mìíràn ń ṣe ohun ńlá, a máa ń gbìyànjú láti ṣe bákan náà. Nígbà tí ó bá jẹ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Jesu, kò yàtọ̀. Kódà, Bíbélì sọ fún wa kí á ní èrò-ọkàn kan náà pẹ̀lú Jesu. Títẹ̀lé Jesu ju ọ̀rọ̀ lásán lọ - ó jẹ́ bí a ṣe ń gbé ayé wa.

Bí ó bá yẹ kí á gbé ayé gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe, báwo gan-an ni Ó ṣe gbélé ayé?

Kì í kàn ṣe ènìyàn rere àti ọmọnìkejì tó dára tí ó ń gbìyànjú láti lọ sí ìsìn déédéé. Ohun tó tayọ ni bí Ó ṣe ń wu Bàbá Rẹ̀ àti bí ó ṣe ṣìkẹ́ àwọn ènìyàn gan-an. Ó pàápàá gbájú mọ́ àwọn tó ti sọnù tí wọn kò sí ní ìgbàgbọ́ nínú ohunkóhun tayọ ohun tí wọ́n lè rí ní ayé.

Jesu ni ọkàn fún àwọn tó sọnù, nítorí náà, láti gbélé ayé bí i Rẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní irú ọkàn kan náà.

Wíwá àti gbígba àwọn ẹni tó sọnù là – èyí tí í ṣe ohun tí Jesu wá láti ṣe àti ohun tí a pè wá láti ṣe pẹ̀lú – ní í ṣe pẹ̀lú yíyára sún tọ àwọn ènìyàn tó ti sọnù. Ó rọrùn láti rí àwọn ẹni tó sọnù ní àyíká wa; ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìpènijà láti wá wọn bí Jesu ti ṣe.

Rò nípa wíwá kọ́rọ́rọ́ ọkọ̀ rẹ̀, tàbí àpamọ́wọ́ rẹ tó sọnù. Ibí ni wíwá ti máa jẹ́ lájorí fún wa. Ohun gbogbo yòókù máa dúró nígbà tí a bá ń wá àwọn nǹkan wọ̀nyí nítorí pé, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa, ìgbésí-ayé wa máa dúró nígbà ti a kò bá ní wọn. Mo ti fi ìgbà gbogbo gbàgbé ibi tí mo fi kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ àti àpamọ́wọ́ mi sí àti pé mo ti sọ wọ́n nù yányán rí. Láìsí owó tàbí káàdì báńkì, o kò lè ra ohunkóhun.

Ní àsìkò yìí wíwá fóònù tó sọnù ti di iṣẹ́ ńlá! Ó ti di pàjáwìrì nítorí pé o kò lè lérò ọjọ́ rẹ láìsí i. wà á sáà máa wá a kiri gbogbo ibi tí o rìn dé ni. Púpọ̀ àwọn irinṣẹ́ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nípa wíwá rẹ̀ náà wà lórí fóònù náà pẹ̀lú. Ó máa ń sábà nílò láti wá àwọn ènìyàn láti bá o wá a, ṣùgbọ́n ó dájú pé o kò lè pè wọ́n lórí fóònù. Kò sì ṣe é ṣe kí o ti há àwọn nọ́ńbà fóònù wọn sórí. Nítorí náà, o gbọ́dọ̀ wá àwọn náà pẹ̀lú lójúkojú.

Lónìí, ìrètí mi nip é àwa gẹ́gẹ́ bí ìjọ yóò tún ìbápàdé wa ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jesu, kí á sì gba iṣẹ́ rẹ̀ láti wá àti láti gba àwọn tó sọnù là bí a ṣe ń gbé ìgbésí-ayé ohun tí ó fi wá lọ́lẹ̀ fún jáde. A kò lè kàn ṣe èyí bí ẹni tí ó ń nájà, ṣùgbọ́n ní ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe, tí ó dàbí wíwá fóònù tó sọnù.

Àdúrà mi nip é wà á di ẹni ìgboyà nínú pípín ìgbàgbọ́ rẹ lẹ́yìn tí o bá ka ìpènijà mi fún ọ. Ìrètí mi tí ó tẹ̀lé èyí ni pé wíwàásù Jesu yóò di iṣẹ́ tí ó tọ́ka rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Àwọn tó ti sọnù ò lóǹkà níta, nítorí náà, ẹ jẹ́ ká lọ! Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí ní wá wọn ká sì sọ fún wọn nípa ìtàn Jesu Kristi, ẹni náà nìkan tí ó lè gbà wọ́n là.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú Ìgboyà

Ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí yóò dì ọ́ ní àmùrè pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà láti wàásù Jesu. Jẹ́ ìmọ̀lẹ̀ láàrin òkùnkùn!

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Willie Robertson fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.harpercollins.com/blogs/authors/willie-robertson