Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú ÌgboyàÀpẹrẹ
Ìgboyà Nínú Iṣẹ́ Náà
Lẹ́yìntí Paulu ṣàlàyé fún àwọn ará Romu tán pé bí ẹ bá gbàgbọ́ tí ẹ sì fi ẹnu yín jẹ́wọ́ pé Jesu ni Olúwa, ẹ ó di ẹni ìgbàlà, ó bèèrè ìbéèrè: báwo ni ẹnìkan ṣe lè képe ẹni tí kò tíì gbàgbọ́ nínú rẹ̀? Àti pé báwo ni wọ́n ṣe lè gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tí wọn ò tíì gbọ́ nípa rẹ̀? Àti pé báwo ni wọ́n ṣe lè gbọ́ láìsí oníwàásù kan tí ó wàásù fún wọn? àti pé báwoni ẹnìkan ṣe lè wàásù bí kò bá ṣe pé a rán an?
Nígbà tí àwọn kan yóò kàn k]o ìhìnrere, púpọ̀ ènìyàn kò till tíì gbọ́ ìròyìn ayọ̀. Ẹnìkan nílò láti sọ fún wọn. kín ní í ṣe tí kì í ṣe ìwọ?
Dídí akéde ìhìnrere wà fún gbogbo wat í a ní à ń tẹ̀lé Kristi. Nígbà tí a bá ní ìgboyà nínú ẹni tí a jẹ́ àti Ti ẹni tí àá ṣe, ìròyìn ayọ̀ yóò sàn jáde nínú wa déédéé àti pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Nígbà tí a bá gbáradì, wíwàásù nípa Jesu máa ń rọrùn si. Nígbà tí a bá mọ̀ pé ìyípadà tòótọ́ láyé lè ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìtàkurọ̀sọ kan ṣoṣo pẹ̀lú ẹnìkan, a ó wá gbogbo àǹfààní láti ní ìtàkurọ̀sọ yẹn. a ó tilẹ̀ ṣẹ̀dá àwọn àǹfààní náà.
Iṣẹ́ rẹ ni láti sọ ìtàn kan – láti fún irúgbìn Ìhìnrere. Ọlọ́run yóò ṣe ìyókù. Máṣe gbà á kanrí nígbà tí ẹnìkan bá lé ọ tàbí tí kò gbọ́ ọ. Jesu tilẹ̀ sọ pé bí wọ́n bá kọ Òun, wọ́n máa kọ ìwọ pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ìyẹnsọ àwọn àsìkò tí àwọn ènìyàn gba ìhìnrere di èyí tó lágbára jùlọ.
Ọ̀kan nínú ibi kíkà lónìí ni ìtàkurọ̀sọ láàrin Filipi àti ìwẹ̀fà ará Etopia, nígbà tí Filipi ń rìnrìn-àjò kiri ní wíwá àǹfààní la’ti wàásù ìròyìn ayọ̀ Jesu. Kíyèsí ìgboyà tí Filipi nib í ó ti ń wàásù bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìyanu pẹ̀lú àjòjì kan. Ó jíṣẹ́ náà fún ẹni tí kò bá pàdé rí, láti orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀, ó sì jẹ́ ara ìdí tí arákùnrin yẹn fi wá Jesu rí.
Ní àwọn ọdún díẹ̀ séyìn, mo ṣe iṣẹ́-ìwádìí díẹ̀ lórí orílẹ̀-èdè Etopia. Lónìí, ẹ̀sìn tí ó tóbi jùlọ níbẹ̀ ni ẹ̀sìn Kristẹni, níbi ti ìdá 63% àwọn ènìyàn tó tó mílíọ́nù 113 ti sọ pé àwọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ nínú Jesu Kristi. Èyí jẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn!
Ìtàn yìí nínú Ìwé Ìṣe lè jẹ́ ibi tí gbogbo rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ fún orílẹ̀-èdè yìí – nípasẹ̀ Filipi, tí a rán jáde láti wàásù Ìhìnrere. A darí rẹ̀ sí ọkùnrin kan tí kò tíì bá pàdé rí ẹni tí kò mọ ohun tí ó ń kà. Filipi dáhùn ìbéèrè rẹ̀, èyí tí yí ayé rẹ̀ padà títí láé tí ó sì yí ìtàn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn mìíràn padà ní orílẹ̀-èdè ìbí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn lónìí.
Sọ ọ́ di isẹ́ rẹ láti mọ Jesu dáadáa. Sọ fún Ọlọ́run láti fi kún ìfẹ́ rẹ sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Bèèrè ìbéèrè ìgboyà nípa ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìtàkùrọ̀sọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn. Jẹ́ ẹnìkan, tí Jesu ń darí, tí a mọ̀ fún wtítan ìròyìn ayọ̀ ká pẹ̀lú gbogbo àǹfàǹí.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí yóò dì ọ́ ní àmùrè pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà láti wàásù Jesu. Jẹ́ ìmọ̀lẹ̀ láàrin òkùnkùn!
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Willie Robertson fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.harpercollins.com/blogs/authors/willie-robertson