Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú ÌgboyàÀpẹrẹ
Ìgboyà Nínú Kristi
A kò lè sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lẹ́yìn Jesu. Ó wá sí ayé ní nǹan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn, ó sì sọ pé òun ni ìtàkùn tó lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ fi ṣe kókó.
Jesu jẹ́ ènìyàn àti Ọlọ́run, tàbí Ọlọ́run ní ìrí ènìyàn. Jesu pe Ọlọ́run ni Bàbá, ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé wíwá òun sí ayé jẹ́ ètò Ọlọ́run fún ọmọnìyàn. Ètò yẹn nílò ìrúbọ ńlá, bí ó ṣe jẹ́ pé Jesu fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún àwọn àìṣedéédéé wa, tàbí ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Bíbélò tip è é. Ìrúbọ̀ Rẹ̀ jẹ́ orísun fún ìrètí wa èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé títun onírùúbọ fún àwọn tí yóò tẹ̀lé E.
Rántí, wówá àti gbígbàlà ni ohun tí Jesu wá ṣe ní ayé. Ìgbàlà náà jẹ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yà wá nípa sí Ọlọ́run. Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn lásán nítorí pé ní ojoojúmọ́, à ń ya àwọn ènìyàn nípa kúrò ní àwùjọ nítorí àwọn ìṣe, ọ̀ràn tàbí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àìṣedéédéé ló wà tó lè yà wá nípa kúrò láwùjọ, ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ tó bá tako òfin Ọlọ́run yà wá nípa kúrò nínú Ìjọba Rẹ̀ tayọ ayé yìí.
Ìròyìn búburú náà ni pé gbogbo w ani a wà ní ìsọ̀rí ẹ̀ṣẹ̀ náà; ìròyìn ayọ̀ náà ni pé Jesu wá láti gbà wá là. Ó wá láti ṣàwárí àti láti gba ẹnikẹ́ni àti gbogbo ẹni tó bá yàn Án là. Wíwá kiri Rẹ̀ ni ó ṣe nípa bíbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀. Ó ń wá àwọn tí yóò gba ara wọn láàyè láti di rírí: àwọn tó ní ìgbàgbọ́ tí wọ́n ń fẹ́ láti gbọ́ràn.
Apá àkọ́kọ́ ìhìnrere ni ikú Jesu fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. A mọ̀ pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe àṣìṣe ńlá, ó ní láti san gbèsè rẹ̀. Ìyẹn kì í ṣe ohun àjòjì fún wa. Gbogbo wa ni a lè ṣe ohun àìdaa. A ré òfin kọjá. A tako ìgbékẹ̀lé. A sọ ohun tó burú jáì. A kùnà.
Gbogbo ètò wa dá lórí títún ara wa ṣe – ìgbófinró, ilé-ẹjọ́, olùgba-owó, ìyànjú ìgbéyàwó, jókòó pẹ̀lú ọ̀gá, ìpàdé àwọn ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́, wọ́n sì lọ bẹ́ẹ̀ jàǹtìrẹrẹ. A máa ń san iye kan fún àsìse wa. Nígbà mìíràn àwọn mìíràn níláti san pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà, àyọrísí yẹ kí ó jẹ́ ìdáríjìn.
Bí kò bá sí ìdáríjìn, a kò ní lè ní àwọn ìbáṣepọ̀ tó ní ìtumọ̀. Láìsí ìdáríjìn, àwọn ìgbéyàwó yóò forí sanpọ́n, wọn yóò fagi lé ìtúndàpọ̀ ìdílé, ìṣubú yóò sì dé bá ìbádọ́rẹ̀ẹ́. Pẹ̀lú ìdáríjìn, aya àti ọkọ á dúró tira wọn, ẹ̀kọ́ ìdílé á tẹ̀síwájú, àwọn ọ̀rẹ́ yóò sì máa fẹ́ ara wọn, gba ara wọn níyànjú lásìkò tó wọ̀ àti àsìkò tí kò wọ̀.
Jesu máa fi ìdáríjìn fún àwọn tó yàn láti ní ìbásẹpọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. A kò kàn gbà wá là tàbí wá wa rí nítorí tí Ó wà. A gbọ́dọ̀ pinnu láti wà ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀.
Nígbà tí o bá yàn láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Jesu, ó máa di ẹni kàn pẹ̀lú Rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí yóò dì ọ́ ní àmùrè pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà láti wàásù Jesu. Jẹ́ ìmọ̀lẹ̀ láàrin òkùnkùn!
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Willie Robertson fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.harpercollins.com/blogs/authors/willie-robertson