Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú ÌgboyàÀpẹrẹ

Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú Ìgboyà

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ìgboyà Nínú Ìgbésẹ̀ Náà

Jesu sọ pé Ẹ̀mí Mímọ́ yóò wá nígbà tí ó kúrò ní ayé. Ìwé Ìhìnrere ti Matiu, Maku, Luku àti Johanu ni ibi tí a ti rí ìtàn ìgbésí-ayé Jesu láti ìgbà ìbí Rẹ̀, ikú sí àjíǹde Rẹ̀. Nínú Ìwé Ìṣe, a kà á pé Jesu gòkè re ọ̀run, Ẹ̀mí Mímọ́ sì yọjú! Peteru dìde ó sì bá ọ̀pọ̀ èrò sọ̀rọ̀ láti wàásù ìhìnrere àti láti jẹ́ kí wọ́n mọ pé Ẹ̀mí Mímọ́ yìí yóò gbé inú àwọn tó bá tẹ̀lé Jesu láti ìgbà yìí lọ.

Peteru wà pẹ̀lú Jesu lásìkò iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, ó sì gbọ́ ohun tí Olúwa sọ, ó sì sọ ọ́ fún àwọn ènìyàn. Lásìkò yìí, ó ń wá ó sì ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn gba ìgbàlà. Ó gbáradì gidi, ó sì fèsì fún ìrètí tí ó ní nínú Jesu. Ó só fún wọn pé Jesu tis an gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe wọn pẹ̀lú ìrúbọ Rẹ̀, ní wíwo bí ọ̀pọ̀ wọn lè ti wà níbẹ̀ láti rí Jesu lórí àgbélèbú.

Peteru sọ ohun tí ó yẹ láti ṣe ni kedere. Ó sọ fún àwọn ènìyàn náà láti ronú piwàdà kí á sì rì wọ́n bọmi.

Ronúpìwàdà túmọ̀ sí láti yípadà – láti yí padà sí ọ̀nà mìíràn. Ó túmọ̀ sí yíyan ìwà-bí-Ọlọ́run bí o bá kúndùn ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí a bá ronúpìwàdà, a dásẹ̀ wọ inú ayé titun a sì bẹ̀rẹ̀ sí ní so èso Ẹ̀mí Mímọ́. Ìrònúpìwàdà ju ohun àfẹnusọ lásán lọ; ó jẹ́ bí o ṣe ń gbé ayé.

Ìrìbọmi túmọ̀ sí títẹ̀ bọ inú omi. Johanu onítẹ̀bọmi náà ti so ìṣe méjéèjì yìí pọ̀ ní mímúrasílẹ̀ fún iṣẹ́-ìránṣe Jesu. Ní àsìkò yìí, Peteru náà fi ọ̀nà ìsọdọ̀tun yìí pẹ̀lú. Kò ṣàlàyé púpọ̀ ṣùgbọ́n ó gba àwọn onígbàgbọ́ titun níyànjú láti ṣe ìtẹ̀bọ̀mi lẹ́yìnìrònúpìwàdà wọn.

Gẹ́gk bí Jesu ti ṣe kú, tí a sìnkú Rẹ̀, tí ó sì jíǹde kúrò nínú òkú, à ń sín In jẹ bí a ṣe ń gbọ́ràn sí ìhìnrere kan náà. Ohun àtijọ́ ti kọjá, ohun titun sì ti jáde. Kíkún fún Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run, a ko tẹ̀síwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ fún oore-ọ̀fẹ́, nítorí tí a kú sí ìgbé-ayé yẹn, a sì ní èso titun tí ó ń so jáde nínú ayé wa.

Níwọ̀n ìgbà tí a tin í Ẹ̀mí Ọlọ́run nínú wa, kò sí ìdálẹ́bi fún ẹ̀ṣẹ̀ wa – tàtẹ̀yìnwá, ti-lọ́ọ́lọ́ọ́, tàbí ti ọjọ́-iwájú. A kò lè dá wa lẹ́bi mọ́ fún ikú ẹ̀mí. A sọ wá di ààyè! Ó jẹ́ ìròyìn ayọ̀ Jesu Kristi tí àwọn ènìyàn nílò nígbà y]en tí wan sì tún nílò lónìí!

Àmọ́ ṣá, ìwọ kò sí nínú ará bíkòṣe nínú ẹ̀mí, bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú rẹ. bí ẹnikẹ́ni kò bá sì ní ẹ̀mí Kristi, kò sí nínú ẹni Kristi.

A lè dára pọ̀ ma Jesu nínú wíwá àti gbígba àwọn tó ti sọnù là nípasẹ̀ bíbẹ̀rẹ̀ ìtakurọ̀sọ, bíbè[rè ìbéèrè àti wíwádìí ipò tí àwọn ènìyàn wà ní ti ìbásepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kí á wá/dù kí á sì ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti si ẹni ìgbàlà.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú Ìgboyà

Ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí yóò dì ọ́ ní àmùrè pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà láti wàásù Jesu. Jẹ́ ìmọ̀lẹ̀ láàrin òkùnkùn!

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Willie Robertson fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.harpercollins.com/blogs/authors/willie-robertson