Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú ÌgboyàÀpẹrẹ

Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú Ìgboyà

Ọjọ́ 2 nínú 5

Ìgboyà Láti Bẹ̀rẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, mo fẹ́ràn láti múrasílẹ̀ àti láti ṣetán nígbà tí mob á ní àǹfààní láti ṣàlàyé ìrètí tí mo ní nínú Rẹ̀. Gbà mí gbọ́, o kò nílò láti jẹ́ onímọ̀ Bíbélì. Èmi pàápàá kì í ṣe é. Ìyẹn báyẹn, níní ìfẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dájúdájú máa ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń wàásù fún àwọn ènìyàn. Bíbélì kún fún àwọn ìtàn ìtàkurọ̀sọ láàrin àwọn ènìyàn. Èyí ń ṣe àfihàn pé Bíbélì lè tọ́ka wọn sí, ó sì lè so wọ́n pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí ní lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí atọ́nà fún ayé wọn.

Lọ́pọ̀ ìgbà kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní ka ìtàn inú Bíbélì fún ẹnìkan, mo fẹ́ gbọ́ ìtàn ayé ẹni náà. Ó rọrùn láti ro èrò nípa ìtàn ẹnìkan nítorí pé gbogbo wa ní ìtàn. Mo ti ṣe àwárí èyí láti jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ tó dára jùlọ. Pípààrọ̀ ìtàn kì í kàn ṣe àsìkò ẹ̀sìn tó yanu, nítorí pé a tilẹ̀ ti máa ń sọ ìtàn ayé wa lójoojúmọ́ nígbàkúùgbà àti níbikíbi tí àwọn ènìyàn bá tin í ìbápàdé pẹ̀lú ara wọn.bí o ṣe ń di ọlọ́kàn iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí i, wà á fẹ́ kí ìtàn rẹ darí lọ sínú ìtàn Ọlọ́run.

Kín ni èrèdí títẹ́tí sí ẹnìkan? Bóyá nítorí pé ó ní ìtàra fún ẹni bẹ́ẹ̀, bí Jesu tin í ìtara fún wa. Ó wá láti wá kiri àti láti gbàlà. Ìkẹ́ ni ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò náà. Nígbà tí a bá síwọ́ ìkẹ́ fún ènìyàn, tàbí tí a bá ń ṣìkẹ́ àwọn kan nìkan, a ti yapa kúrò nínú iṣẹ́-ìránṣẹ́ Jesu. Lọ́jọ́ tí ayé wa bá wá sí òpin, àwọn tí a bá ti fọwọ́ tọ́ tí a sì ní àsopọ̀ mọ́ nìkan ni yóò nítumọ̀ jùlọ. Òtítọ́ máa ń jẹ jáde nígbà tí a bá lọ síbi ìsìnkú ẹnìkan. Ohun tí wọ́n sọ, ohun tí wọn kò sọ, àti ẹni tí ó wá bínú àti ẹni tí ó wá ṣe àpọ́nlé, gbogb wọn ló ń sọ irúfẹ̀ ayé tí ẹni náà gbé.

Gbogbo wa ni a ní ìtàn ìrìnàjò tiwa ní ayé. Àwọn ìtàn ìgbésí-ayé kan lágbára, àwọn kan kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára. Tìrẹ lè y ani lẹ́nu kí ó sì lárinrin, tàbí kí ó banújẹ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìbàjẹ́ tàbí ìpinnu tí kò dára. Bóyá ó si jẹ́ àpapọ̀ méjéèjì. Síbẹ̀, o kò ní mọ ìtàn àwọn mìíràn àfi bí o bá bèèrè.

Fún ìdí èyí, bíbèèrè ìbéèrè ni ìpele tí ó pé jùlọ níbi tí ó yẹ kí o ti bẹ̀rẹ̀ pínpín ìgbàgbọ́ rẹ. àwọn ìbéèrè tí kò le bí i, ‘níbo ni o ti sẹ̀ wá?’ tàbí ‘Ǹjẹ́ o ní ẹbí?’tàbí ‘báwo ni ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ rẹ ṣe rí?’ jẹ́ àwọn ìbéèrè tó wọ́pọ̀ tí gbogbo wa máa ń bèrè láti bẹ̀rẹ̀ ìtàkurọ̀sọ pllú ènìyàn titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ pádé. Mo rí i pé bíbèèrè ìbéèrè rọrùn púpọ̀, ó sì máa ń fẹ́rẹ̀ yọrí sí òtítọ́. Níbí ni ìgbáradì wa ti lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi èsì fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bi wá ní èrèdí ìrètí tí a ní. Ìlànà yìí ni ó ya ìtàkurọ̀sọ ojoojúmọ́ sọ́tọ̀ sí ìtàkurọ̀sọ ìmọ̀ọ́mọ̀ṣe adálórí-ìhìnrere.

Bí a bá ń gbìyànjú láti wádìí bóyá ẹnìkan ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Olúwa, a jẹ́ pé a níláti mọ bí ìbáṣepọ̀ náà ṣe ń ṣiṣẹ́. Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ nípa wíwo bí a ṣe ń ṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ènìyàn àti bí wọ́n ṣe lè gbòòrò si.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Wíwàásù Jesu Pẹ̀lú Ìgboyà

Ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí yóò dì ọ́ ní àmùrè pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà láti wàásù Jesu. Jẹ́ ìmọ̀lẹ̀ láàrin òkùnkùn!

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Willie Robertson fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.harpercollins.com/blogs/authors/willie-robertson